Tẹlifísàn Kwara bẹ̀rẹ iṣẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélógún - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 2, 2022

Tẹlifísàn Kwara bẹ̀rẹ iṣẹ́ wákàtí mẹ́rìnlélógún


Idunnu ti ṣubu lu ayọ gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara bayii, lori bi ileeṣẹ tẹlifiṣan ipinlẹ naa, Kwara TV ṣe bẹrẹ iṣẹ alaṣeyipo, iyẹn wakati mẹrinlelogun, lai dawọ duro.
 
Yatọ si eyi, ohun to n mu kawọn eeyan maa gba ilu ati ijo lati dawọ idunnu ni bi wọn tun ṣe gun ori ikanni StarTimes 'Channel 113', ati FreeTV 502.

Ọjọ Iṣẹgun tii ṣe Tusidee, ọsẹ yii la gbọ pe ileeṣẹ tẹlifiṣan naa bẹrẹ iṣẹ lakọtun fun igba akọkọ, eyi ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq dari rẹ.
 
Itan nla tuntun ni ipinlẹ naa tun fi lọlẹ yii, nitori pe lati bi ogun ọdun le ti wọn ti da ileeṣẹ tẹlifiṣan yii silẹ, wọn ko ṣiṣẹ wọ wakati mẹrinlelogun ri, igba kọkọ rẹe.
 
Bakan naa la gbọ pe igbesẹ nla ti bẹrẹ lati gun ikanni DSTV, fun igbadun gbogbo araalu, paapaa awọn ọmọ ipinlẹ naa ti wọn wa kaakiri agbaye, lati mọ ohun to n lọ nipinlẹ wọn.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI