Lonii, Ọjọru, Wẹsidee ni ile igbimọ aṣofi ipinlẹ Zamfara yọ igbakeji gomina wọn, Ọgbẹni Mahdi Gusau danu, ti wọn si tun paṣẹ pe gbogbo ẹtọ to tọ si i ni ko dawọ duro lai fi akoko ṣofo.
Ṣaaju akoko yii la gbọ pe ile igbimọ naa ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣe agbeyẹwo awọon ẹsun ti wọn fi kan Gusau, eyi ti wọn pata tẹwọ gba lonii.
Adajọ agba nipinlẹ naa, Onidajọ Kulu Aliyu, ni alaga igbimọ ọhun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Ọmọ ile igbimọ aṣofin ogun ninu awọn mẹrinlelogun la gbọ pe wọn dibo lati yọ Gusau danu.
No comments:
Post a Comment