Gbajugbaja onkọrin nni, Ṣeun Kuti, ẹni to tun jẹ ọkan lara awọn ọmọ agba olorin Afro nni, Oloogbe Fẹla Anikulapo Kuti ti jẹ ko di mimọ pe pupọ awọn baba alaye, baba olowo ti wọn n jaye kaakiri lo jẹ pe oogun owo ni wọn ṣe.
O sọ pe ko ti i si ọmọ ilẹ adulawọ kan to ni owo gidi lai ki i ṣe pe oogun owo ni iru ẹni bẹẹ ṣe, o ni ṣe ni wọn paayan lati fi lowo.
Ṣeun Kuti lo sọrọ yii jade lori ikanni ayelujara ti Insitagiraamu rẹ laipẹ yii, to si n bẹ awọn eeyan pe ki wọn jawọ ninu iwa buruku to n doju ti ni naa.
"Ẹ ma ṣe ṣe oogun owo. Ẹ ma ṣe paaya nitori owo. Ẹ jọwọ, ọmọ ilẹ adulawọ wo ni ki i pa awọn eeyan nitori owo?
“Ida mọkandinlọgọrun-un ọrọ to wa ni Naijiria lo jẹ pe nipa fifi ẹmi ati ayanmọ ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ Naijiria ni. Oogun owo gidi niyẹn!!
“Abi ka sọ pe ojulasan ni ile fi n da wo ni, ti ileewe n wo pa awọn ọmọ? Gbogbo awọn ẹmi ti opopona ti ko dara n mu lọ nkọ? Awọn aṣkupani to wa ni ọsibitu wa kaakiri nkọ?
“Ẹ gbọ mi, Naijiria gan-an funra rẹ, oogun owo ni! Awọn baba ati iya alaye lo jẹ pe afiniṣẹṣo ni wọn jẹ..
“Abi ka sọ pe oju lasan ni aṣerunloge fi di gbajugbaja elepo rọbii ni? Ẹ jọwọ, ẹ sun jare.
No comments:
Post a Comment