Ọmọ ọga agba Poli tẹlẹ dero ẹwọn lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo' n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 4, 2022

Ọmọ ọga agba Poli tẹlẹ dero ẹwọn lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo' n'Ilọrin


Ọkan lara awọn ọga agba tẹlẹri nile ẹkọ gbogboniṣe tilu Ọffa, iyẹn Federal Polytechnic, Offa, Ọlaoye Jamiu Ọlanrewaju lo ti wa lahamọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC bayii lori ẹsun jibiti ori ayelujara ati gbajuẹ.

Ọlanrewaju, pẹlu awọn meji kan, Badmus Ridwan Moyọsọrẹ toun jẹ ọmọ bibi ilu Ibadan ati Abdulsalam Ibrahim toun wa lati ilu Malete nijọba ibilẹ Moro, ipinlẹ Kwara ni wọn jọ wa lahamọ EFCC.

A gbọ pe Ọjọbọ, Tọsidee ana lawọn mẹtẹẹta wọnyi foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun jibiti ati gbajuẹ lori ayelujara.
 
Wọn lawọn mẹtẹẹta yii ni wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn niwaju Onidajọ Adenike Akinpelu ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara to wa nilu Ilọrin





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI