Lati le tubọ pana wahala ọrọ Ijaabu to n waye kaakiri ileewe girama nipinlẹ Kwara, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii, ti gbe igbimọ ẹlẹni mejila kan kalẹ ti yoo ri sọrọ wahala ọhun.
Igbimọ naa ti wọn pe ni Inter-Religious Council (IREC), la gbọ pe o kun fun awọn agbaagba, ọjọgbọn, ati alẹnulọrọ lawujọ, paapaa lẹka ẹsin gbogbo.
Ẹmir tilu Shonga, to gbajumọ nipa aawọ yiyanju, Ọmọwe Haliru Yahya Ndanusa ni alaga igbimọ ọhun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Awọn miran to wa ninu igbimọ ọhun ni Onidajọ Idris Haroon; Onidajọ Ọlatunji Bamgbọla; amugbalẹgbẹ pataki fun gomina lori ọrọ ẹsin Islam, Zubair Ibrahim Dan Maigoro; ẹni ti wọn fẹẹ yan fun ipo amugbalẹgbẹ gomina lori ọrọ ẹsin Kristẹẹni; Kọmiṣanna fọrọ eto-ẹkọ tẹlẹri, Hajia Halimat Yusuf; akọwe agba tẹlẹri, Ọmọwe Rhoda Ajiboye; Ọmọwe Soburu Alaaya; Moses Lasisi Abegunde; Ọjọgbọn Feyi Grace Adepọju; Alagba Stephen Wọle Oke; ati alakoso ileeṣe akanṣe iṣẹ, Iṣhọla Maryam Idowu, ti yoo jẹ akọwe.
Igbimọ yii la gbọ pe wọn yoo ṣiṣẹ papọ lati rii pe awọn ẹlẹsin mejeeji yoo wa ni iṣọkan, ti wọn yoo si gba alaafia laaye laaarin ara wọn.
No comments:
Post a Comment