Lojuna lati jẹ ki opopona ti afara Ọgagun Babatunde Idiagbọn wa, ijọba ipinlẹ Kwara ti kede sita wi pe awọn ti ti i pa, bẹrẹ lati Ọjó Iṣẹgun, Tusidee ana, titi di ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.
Agogo mẹwaa aarọ ana ni ijọba Kwara ti afara naa pa, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ti wọn yoo si ṣi i pada laago mẹwaa alẹ, ọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2022 ti a wa yii.
Afara naa lo wa ni ikorita garaaji Tipper, iyẹn Tipper Garage to gbajumọ daadaa nilu Ilọrin,, to jẹ olu-ilu ipinlẹ naa.
AWIKONKO gbọ pe eyi yoo fun awọn agbaṣẹṣe lanfaani lati tete pari atunṣe afara naa.
Ijọba ipinlẹ naa wa n rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn araalu, paapaa awọn to n gba afara yii lojoojumọ lati dakun wa ọna miran ti wọn yoo maa gba titi digba ti atunṣe ọhun yoo fi pari, ati pe fun irọrun araalu naa ni igbesẹ ọhun da le lori.
No comments:
Post a Comment