'Màjíìkì' ni Tinubu máa fi tún Nàìjíríà ṣe bí wọ́n bá dìbò fun un - Sanwo-Olu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 19, 2022

'Màjíìkì' ni Tinubu máa fi tún Nàìjíríà ṣe bí wọ́n bá dìbò fun un - Sanwo-Olu


Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ti sọ pe majiiki ni aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Ahmed Tinubu yoo fi yọ Naijiria kuro ninu iṣoro ati wahala, iyẹn bi awọn ọmọ orileede yii ba fi dibo yan-an lọdun 2023.

Sanwo-Olu sọ pe Tinubu mọ gbogbo awọn iṣoro ati adojukọ to n ba orileede Naijiria finra, to si ni baba naa ni ọna abayọ lọwọ lati fi gba Naijiria silẹ.

Ilu Eko ni Sanwo-Olu ti sọrọ yii, to si rọ gbogbo awọn ọmọ Naijiria lati fun Tinubu laaye lati di Aarẹ orileede yii lọdun to n bọ.

Nibẹ lo tun ti gba awọn aṣofin ipinlẹ Eko lamọran lati ṣiṣẹ takuntakun, eyi ti yoo jẹ ki Tinubu de ipo Aarẹ.

"Tinubu mọ awọn ohun to n ba orileede wa finra bi ẹyin ọwọ rẹ, bẹẹ lo si ni majiiki ti yoo fi ṣe atunṣe rẹ lọwọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI