Muyiwa Adejọbi di agbẹnusọ ọlọpaa Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 13, 2022

Muyiwa Adejọbi di agbẹnusọ ọlọpaa Naijiria


Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria labẹ ọga patapata wọn ti kede Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi gẹgẹ bi agbẹnusọ agba, to si ni iṣẹ ti bẹrẹ lai fi akoko ṣofo rara.
 
Ọjọ Abamẹta, Satide ana ni ileeṣẹ ọlọpaa kede Ọmọọba Adejọbi, ẹni to tun jẹ CSP (Chief Superintendent of Police), to di ipo igbakeji agbẹnusọ ọlọpaa agba mu tẹlẹ, wi pe ko maa ba iṣẹ lọ.
 
Frank Mba to wa nipo ọhun tẹlẹ la gbọ pe ọga ọlọpaa yan lati lọ kẹkọọ awọn agba, iyẹn Senior Executive Course siwaju sii nile-ẹkọ National Institute for Policy and Strategic Studies (NIPSS), to wa ni Kuru, ilu Jos, ipinlẹ Plateau.
 
Ọmọọba Adejọbi lo ti figba kan ri jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, iyẹn laaarin ọdun 2008 si 2016; lẹyin to kuro nibẹ lo di agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun ti Zone 2, to wa ni Onikan l'Ekoo, lọdun 2016; lẹyin eyi lo di agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko laaarin oṣu kẹsan-an, ọdun 2020 si oṣu kẹjọ, ọdun 2021, to si ko ipa ribiribi.
 
Olumuyiwa Adejọbi, kuro nibẹ, o gba ilu Abuja lọ, nibi to ti lọo di igbakeji agbẹnusọ ọlọpaa agba orileede yii, awọn akitiyan rẹ lo mu ki ọga ọlọpaa paṣẹ pe ko tẹsiwaju lati di agbẹnusọ apapọ fun ileeṣẹ ọlọpaa orileede yii.
 
Adejọbi kẹkọọ gboye ni fasiti ilu Ibadan pẹlu imọ Archeology and Geography (Combined Honours). o tun gba iwe ẹri Masters ni ẹka yiyanju aawọ ati gbigba alaafia laaye, iyẹn Peace and Conflict Studies ni fasiti Ibadan kan naa.
 
Ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹgbẹ Nigerian Institute of Public Relations (NIPR); International Public Relations Association (IPRA); Pointman Leadership Institute, USA; International Association of Chiefs of Police (IACP), USA; ati Institute of Corporate Administration, Naijiria ni Ọmọọba Adejọbi jẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI