Lẹ́yin ọdún méjìlá, Tóbi Joseph fi rédíò RockCity sílẹ̀, ó lásìkò tó láti dá dúró - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 7, 2022

Lẹ́yin ọdún méjìlá, Tóbi Joseph fi rédíò RockCity sílẹ̀, ó lásìkò tó láti dá dúró


Ọkan pataki lara awọn ilu mọ-ọn-ka sọrọsọrọ oloyinbo nni, Oluwatobilọba Daniel Joseph, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Tobi Joseph lo ti kede sita lonii, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu kejei wi pe oun ti fi ileeṣẹ redio agbohusafẹfẹ nni, RockCity 101.9FM silẹ.
 
Nigba to n kede lori ikanni ayelujara ti Fesibuuku rẹ laarọ oni, Tobi Joseph jẹ ko di mimọ pe ipinnu naa kii ṣe ohun to rọrun fun akikanju eeyan lati ṣe, ṣugbọn lati le tẹsiwaju nidii iṣẹ yii lo jẹ koun kọwe fiṣẹ silẹ.

O ni asiko naa ti to foun lati da duro, ki ayanmọ ati ipinnu oun le wa si imuṣẹ.
 
Joseph, ẹni to de ileeṣẹ redio RockCity, nibi to ti bẹrẹ iṣẹ igbohunsafẹfẹ lọdun 2010 lo n kuro nibẹ pẹlu ipo olori ikọ igbohunsafẹfẹ ati alakoso eto (Head of Presentation, Programs).
 
O dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ, awọn ọga rẹ nileeṣẹ redio naa, ati gbogbo awọn ololufẹ rẹ patapata.
 
Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe oun yoo sọ ibi toun yoo tun ti maa ṣiṣẹ laipẹ fun gbogbo awọn araye, paapaa awọn ololufẹ oun.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI