Lẹyin ọdun kẹta! Ọṣinbajo tun ranti 'Ọjọ m ba ku' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 2, 2022

Lẹyin ọdun kẹta! Ọṣinbajo tun ranti 'Ọjọ m ba ku'


Igbakeji Aarẹ orileede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo tun ti ṣe iranti ọjọ naa ti ko ba padanu ẹmi rẹ sinu ijamba ọkọ ofurufu agberapa, iyẹn Helicopter, eyi to ja lori irin nilu Kabba, ipinlẹ Kogi.
 
Ọjọgbọn Ọṣinbajo ati awọn aṣiwaju orileede yii kan ni wọn jọ wa ninu ọkọ baluu agberapa ọhun lọjọ keji, oṣu keji, ọdun 2019 lakooko to ja.

Ibi ipolongo idibo ni Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo atawọn eeyan naa n lọ nigba naa, ko to di pe baluu yii ja lulẹ lojiji, to si tun gbina.
 
Ọṣinbajo nigba to n sọrọ sọ pe 'ọjọ ibanujẹ' ni ọjọ naa ko ba jẹ, ṣugbọn toun dupẹ lọwọ Ọlọrun to pa oun mọ kuro lọwọ ewu.
 
“Ṣugbọn inu mi dun, mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun wi pe ọjọ naa wa di ọjọ iṣẹgun ati idupẹ." Ọṣinbajo sọrọ.
 
Nigba tọ gbe ọrọ naa sori ikanni ayelujara lati ọwọ agbenusọ rẹ, Laolu Akande, sọ pe:
 
"Ogo ni fun orukọ Ọlọrun! Oni lo pe ọdun mẹta geerege ti ỌL|ORUN ko igbakeji Aarẹ ati awa mọkanla yọ nilu Kogi, nigba ti ọkọ baluu agberapa wa deede ja lulẹ! Ẹ darapọ mọ wa lati yin Ọlọrun, ẹni to ko wa yọ nipa Ogo rẹ, ẹni to si le ṣe tayọ imọ ẹnikẹni, kọda kọja ohun ti a beere fun, paapaa ohun ti a ko lero! ỌPẸ NLA"

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI