Ile-ẹjọ ECOWAS bẹrẹ iṣẹ lakọtun ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 23, 2022

Ile-ẹjọ ECOWAS bẹrẹ iṣẹ lakọtun ni Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana ti fi ile-ẹjọ ECOWAS lọlẹ, ti wọn si ti bẹrẹ iṣẹ lẹkunrẹrẹ lai ni idiwọ tabi idena kankan ninu.

Wọn ni lati fi ẹsẹ ofin mulẹ, ati lati jẹ ki awọn eeyan maa tẹle ilana ofin lo fa idasilẹ ile-ẹjọ naa, ati pe ile-ẹjọ alagbeeka ni yoo jẹ.

Nigba to n gba ẹnu Gomina AbdulRazaq sọrọ, igbakeji gomina, Ọgbẹni Kayọde Alabi, jẹ ko di mimọ pe ile-ẹjọ naa yoo maa yanju awọn aawọ to ba n waye lawọn agbegbe kọọkan.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI