Ọjọ Satide, Abamẹta, ọsẹ yii ni eto gbalegbata yoo waye kaakiri ipinlẹ Kwara, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n ṣe ni gbogbo ọjọ Abamẹta to ba gbẹyin oṣu.
Ijọba Kwara lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade ti Ọnarebu Abọsẹde Ọlaitan Buraimọh, iyẹn kọmiṣanna fọrọ eto ayika gbe jade laipẹ yii, nibi to ti n jẹ di mimọ pe aarin agogo meje aarọ si agogo mẹsan-an aarọ ni eto ọhun yoo fi waye.
O ni asiko naa ni gbogbo awọn araalu yoo ṣeto imọtoto ayika ati agbegbe wọn, leyi ti yoo mu idena ba ajakalẹ arun ati oniruuru aisan gbogbo.
Ninu atẹjade ọhun ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti jẹ ko di mimọ pe eto yii ko yọ ẹnikẹni silẹ, ati pe gbogbo ile ati ileeṣẹ, to fi mọ ibi tawọn eeyan ti n ṣe ọrọ aje wọn ni wọn gbọdọ ṣe imọtoto rẹ pata.
O ni awọn agbofinro yoo maa lọ kaakiri lati ṣe abojuto bi nnkan ṣe n lọ , ati pe ẹni ti wọn ba ri, ti ko kopa ninu eto ọhun yoo foju winna ofin.
No comments:
Post a Comment