Idibo 2023: Ẹsan n bọ wa ke - Wolii Ayọdele ṣe ikilọ nla fun Tinubu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 2, 2022

Idibo 2023: Ẹsan n bọ wa ke - Wolii Ayọdele ṣe ikilọ nla fun Tinubu


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church lorileede Naijiria, Wolii Elijah Ayọdele, lonii, Ọjọru, Wẹsidee ti sọ pe ẹsan iwa ti Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Bọla Ahmẹd Tinubu ti hu sẹyin n bọ laipẹ lati ke lori rẹ.
 
O ni ko ṣọra fun gbigbe apoti lati du ipo Aarẹ orileede yii, nitori pe kii ṣe ẹru rẹ rara.

Wolii Ayọdele lo sọrọ yii ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Ọṣhọ Oluwatosin, gbe jade lọsan oni, Wẹsidee, to si ni gbogbo awọn aṣepamọ Tinubu lo n bọ wa foju han nita gbangba.
 
O ni awọn eso ti ko dara, eyi ti Aṣiwaju Tinubu ti gbin lati ọdun pipẹ lo n bọ wa ruwe jade sita, ti yoo si foju han si gbogbo aye.
 
Wolii Ayọdele sọ pe ṣe ni Aṣiwaju Tinubu ja agbara gba lọwọ awọn aṣiwaju kan, nitori ti ara rẹ nikan, nnkan wọnyi ni yoo si pada wa ṣẹlẹ soun naa, ayafi bi Ọlọrun ma foju aanu wo o.
 
"Tinubu ti gbin awọn eso kan ti ko dara, asiko yii si ni yoo kore awọn eso naa, awọn eso wọnyi ko dara to, ẹsan si n bọ wa ke. Awọn to gbe dide ni yoo dalẹ rẹ. Mo rii wi pe awọn nnkan buburu to ti ṣe sẹyin n dọdẹ rẹ.

"Ninu irin ajo oṣelu rẹ, o ti ja agbara gba lọwọ awọn aṣiwaju kan, nnkan to ṣe yii naa n bọ wa ṣẹlẹ si i ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
 
"Ko nilo lati tun ja fitafita fun ọjọ iwaju oṣelu rẹ mọ, ẹsan n bọ wa ke lori ọkan irin ajo oṣelu rẹ. Aanu Ọlọrun nikan lo le gba a silẹ lọwọ awọn nnkan to f'ẹ ṣubu luu."
 
Siwaju sii ni Wolii Ayọdele tun sọ pe: 
"Ọlọrun nifẹẹ Tinubu to pọ, ṣugbọn ko fẹran ara rẹ. Mi o kii ṣe ọta Tinubu, mo nifẹẹ rẹ, mi o si ni nnkankan pẹlu rẹ. Mo nifẹ si pupọ awọn nnkan rẹ, ṣugbọn mo ni lati sọ ọkan Ọlọrun nipa afojusun rẹ.
 
"Mo fẹ ko tun lọ fi ẹmi wadii lọdọ awọn Wolii miran kaakiri. Bi wọn ki ba a ṣe alatẹnujẹ, wọn yoo sọ otitọ ọrọ fun un."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI