EKOEXCEL pè fún gbígbé èdè abínibí lárugẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 21, 2022

EKOEXCEL pè fún gbígbé èdè abínibí lárugẹ


Fun bi ayajọ ede abinibi ṣe n waye lonii, ọjọ Aje, Mọnde, ajọ EKOEXCEL ti sọ pe ojuṣe gbogbo wa ni lati ri i pe ede abinibi ko lọ si oko iparun. 

Ajọ yii ti ṣeleri pe gbogbo ọna loun yoo gba lati ri i daju pe Ina ede abinibi ko jo ajo rẹyin nipinlẹ Eko, paapaa lawọn ileewe alakọbẹrẹ ati girama wa. 

Ajo yii lohun ko ni i kaarẹ lati ri i pe ede abinibi di itẹwọgba laarin awọn akẹkọọ ati lawujọ wa ki iwa ọmọluabi le e gbilẹ si i laarin awọn eeyan.

EKOEXCEL ninu ọrọ ẹ fun ayajọ ede abinibi tọdun yii pẹlu akọle apileko to lọ bayii 'Lilo ẹrọ igbalode lati kọ nipa awọn ede, akude ati anfaani to wa nibẹ' lo ti tẹ siwaju ninu ọrọ ẹ pe asiko ti to ti gbogbo awọn ọmọ wa yoo mọ anfaani ati ibukun to wa ninu ki wọn gbọ ede abinibi, eyi ti ko ni i yọ ọmọ kankan silẹ.

Ninu ọrọ ẹ, alaga ajọ LASUBEB, Ọnọrebu Wahab Alawiye-King, sọ pe gbogbo awọn olukọ to wa labẹ ajọ EKOEXCEL ni wọn n lo ede abinibi lati kọ awọn akẹkọọ wọn.

O fi kun ọrọ ẹ pe lilo ede abinibi lati kọ ọmọ jẹ ọna kan gboogi lati jẹ ki ipinlẹ Eko iru ọmọ bẹẹ rese wale daadaa. 

Alaga yii tẹ siwaju ninu ọrọ ẹ pe eto kan ti Oloogbe Ọjọgbọn Aliu Babatunde Fafunwa gbe kalẹ ti wọn pe ni 'The Ife Six Years Primary Project' fihan pe ọmọ ti wọn ba kọ lede abinibi maa n ja fafa ninu ẹkọ wọn ju awọn akẹgbẹ wọn lọ. 

Bẹẹ lo han gedegbe pe ọmọ ti ko ba gbọ ede abinibi ko le e mọ bi wọn ti n sọ ede gẹẹsi daadaa. 

Ọnarebu Alawiye-King fi kun ọrọ ẹ pe awọn ko fẹ ki awọn ogo ọjọ iwaju orileede yii kan maa sọ ede gẹẹsi la i ni naani ede ati aṣa awọn to bi wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI