Aarẹ Muhammadu Buhari ti ba ọkan lara awọn aṣofin orileede Naijiria tẹlẹri, Sẹnetọ Ben Murray-Bruce kẹdun iku mama rẹ, Arabinrin Margaret Murray-Bruce to jade laye lẹni ọdun marundinlaadọrun-un.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Buhari lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Garba Ṣhehu, gbe jade lonii, Ọjọru, Wẹsidee, o sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ fun ijọba orileede yii lati gbo iroyin iku obinrin naa to gba ọrọ ẹsun mu tọkantọkan.
O ni akikanju gidi ni oloogbe naa, ati pe ipa to ko ninu idagbasoke orileede Naijiria nipa titọ awọn ọmọ ti kii ṣe tiẹ, to si kọ wọn ni ọna Ọlọrun ko ṣee gbagbe titi lai.
No comments:
Post a Comment