Biṣọọbu Oyedepo rọjo epe le awọn Fulani darandaran, ajinigbe lori - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 22, 2022

Biṣọọbu Oyedepo rọjo epe le awọn Fulani darandaran, ajinigbe lori


Biṣọọbu David Oyedepo, ti ijọ Living Faith Church Worldwide, eyi ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Winners lo ti rọjo epe le awọn Fulani darandaran, ajinigbe atawọn agbebọn lori, to si ni iku oro ni gbogbo wọn maa ku.
 
Yatọ si awọn wọnyii, Wolii Oyedepo sọ pe gbogbo awọn to n da wahala silẹ lorileede Naijiria, ti wọn ko fun Naijiria ni isinmi ni wọn maa kagbako nla lọwọ awọn ọmọ ogun ọrun.

Nibi iwaasu kan ni Biṣọbu Oyedepo ti gegun fun gbogbo awọnn ajinigbe, atawọn to n ṣagbatẹru wọn, to si ni makan lawọn ọmọ oun jẹ fun wọn.
 
 
O ni bi wọn ṣe n kuna lati maa fi awọn ti wọn n jigbe silẹ ni wọn yoo pade iku ojiji.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe, “Ẹyin ajinigbe, ẹ tun gbọ eleyii lẹẹkan si i, ẹnikẹni to ba fọwọ kan eyikeyi ninu awọn ọmọ Winners, yoo padanu ẹmi rẹ sọrun apaadi. Mo fi gbongbo iṣẹ buruku yin gegun. Mo fi gbogbo awọn to n ba a yin dowopọ gegun, mo tun fi gbongbo awọn to n ṣagbatẹru yin gegun.
 
“Ẹyin Fulani darandaran, mo mọ pe ẹ gbọ oyinbo ti mo n sọ. Gbogbo awọn to wa labẹ igbekun yin bayii, ti wọn ni ayẹwo yii lara, ni ki ẹ fi silẹ laaarin ọjọ meje, tabi pe ki ẹ fi ẹ fi ẹmi yin di.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI