Ayederu pasitọ to fipa ba ọmọ ijọ rẹ laṣepọ lakooko itusilẹ ti ha o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 23, 2022

Ayederu pasitọ to fipa ba ọmọ ijọ rẹ laṣepọ lakooko itusilẹ ti ha o


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ayederu pasitọ ṣọọṣi kan ti wọn pe ni Life and Power Bible Church to wa nilu Ogijo, ipinlẹ Ogun, Mathew Ọladapọ.
 
Igbe 'ẹ ṣe mi jẹjẹ, ẹ ṣaanu mi' ni Mathew n pa ni kete ti aṣiri rẹ tu sita, wi pe o fipa ko ibasun fọmọ ọdun mọkandinlogun.
 
Obinrin ọhun ti a fi orukọ bo laṣiri lo ṣalaye fawọn ọlọpaa wi pe Mathew loun riran soun, ati pe oun yoo nilo lati wa ṣe itusilẹ ara-ọtọ.
 
O ni ṣe ni Mathew sọ foun wi pe ọkọ ọrun ni ko jẹ koun ri ololufẹ, iyẹn logunjọ, oṣu yii. O ni Mathew loun gbọdọ gba aawẹ ati adura ọlọjọ mẹta gbako, ati pe inu ṣọọṣi ni yoo ti ṣe e pẹlu igbele ọjọ mẹta.
 
Bẹẹ lo tun sọ pe Mathew ni koun mu owo ẹgbẹrun kan naira dani pẹlu igo ororo kan.
 
Lọjọ ti aawẹ ati adura yii maa bẹrẹ, wọn ni ṣe ni Mathew mu obinrin yii wọ yara kan lọ, nibi to ti sọ pe ko bọ ara rẹ sihooho ọmọluabi, ko si dubulẹ sori asọ kan to tẹ silẹ, eyi toun naa ṣe bẹẹ.
 
Nibi ti ọmọbinrin yii dubulẹ si ni Mathew ti n fi ororo pa gbogbo ara rẹ, to si tun ki ọwọ bọ abẹ rẹ. Nibẹ ni omobinrin yii ti pariwo sita, to si fẹẹ sare dide.

Wọn ni ṣe ni Mathew raga bo o mọlẹ, to si fipa ba a laṣepọ. igba ti oju rẹ walẹ, lo bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki ọmọbinrin naa ma ṣe tu aṣiri sita, ṣugbọn tiyẹn pada gba teṣan ọlọpaa Ogijo lọ.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii tẹsiwaju, ki wọn si lọ foju Mathew ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI