Ile-ẹjọ Majisireeti to fikalẹ si adugbo Iṣabọ to wa nijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta, nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ti ju awọn gbajugbaja oloṣelu meji kan, Adewale Ogundele ati Ibrahim Amọjẹ, sẹwọn ọdun kọọkan gbako lori ẹsun lilo ibọn lọna ti ko tọ.
Adewale ati Ibrahim lọwọ tẹ ni Aafin Alake tilẹ Ẹgba lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja.
Ibi ipade gbogboogbo ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ṣe lọwọ ti tẹ awọn mejeeji yii pẹlu ibọn. Ko to di pe ileeṣẹ ọlọpaa foju wọn ba ile-ẹjọ.
Onidajọ O. O. Adebọ ninu idajọ rẹ sọ pe awọn ẹri toun ri gba nipa awọn mejeeji yii kọja ohun ti wọn n fọwọ bo mọlẹ, to si ni wọn gbọdọ lọ jiya ẹṣẹ wọn nipa ẹwọn ọdun kan gbako, ati iṣe aṣekara.
Onidajọ O. O. Adebọ ninu idajọ rẹ sọ pe awọn ẹri toun ri gba nipa awọn mejeeji yii kọja ohun ti wọn n fọwọ bo mọlẹ, to si ni wọn gbọdọ lọ jiya ẹṣẹ wọn nipa ẹwọn ọdun kan gbako, ati iṣe aṣekara.
No comments:
Post a Comment