Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ọkan lara awọn akẹkọọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ to wa nilu Ile-Ifẹ, Heritage Ajibọla Ayọmikun ku iku oro, nipa bo ṣe jabọ sinu ṣalanga, to si gbabẹ lọ si ajule ọrun, sibẹ gbogbo awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ ni wọn n beere fun idajọ ododo.
Ọsẹ to ṣẹṣẹ n pari lọ yii la gbọ pe Heritage, to wa ni ẹka ikẹkọọ ede ilẹ adulawọ, iyẹn Linguistics and African Languages, ṣeeṣi jabọ sinu ṣalanga naa lakoko toun pẹlu ọrẹ kan n sa asọ sori ikọọ.
Awọn to fi iṣẹlẹ yii to wa leti sọ pe o gba awọn panapana ni wakati kan gbako, ki wọn to debi iṣẹlẹ yii, ti a si gbọ pe fun bi ọgbọn iṣẹju ni wọn lo lati rii yọ.
Ẹpa ko boro mọ nigba ti wọn yoo fi gbe e jade.
No comments:
Post a Comment