Awọn Agbẹkọya lawọn ṣetan lati foogun abẹnugọngọ gbe Igboho jade kuro lẹwọn to wa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 6, 2022

Awọn Agbẹkọya lawọn ṣetan lati foogun abẹnugọngọ gbe Igboho jade kuro lẹwọn to wa


Ẹgbẹ awọn Agbẹkọya lorileede Naijiria ti sọ pe asiko ti to fun wọn bayii lati jẹ ki gbogbo agbaye mọ agbara ti wọn ni nipa oogun abẹnugọngọ.
 
Wọn ni pẹlu bi nnkan ṣe n lọ lori ọrọ olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ tọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho, afi ki awọn tete jẹ ki ijọba apapọ Naijiria mọ pe ilẹ Yoruba ṣi ni oogun abẹnugọngọ to daju.
 
Aarẹ ẹgbẹ Agbẹkọya, Oloye Kamọrudeen Okiki Arẹmu lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii, to fi ni bi ijọba Naijiria ko ba tete fi Sunday Igboho silẹ nibamu pẹlu ilana ofin, awọn ṣetan lati fi agbara ibilẹ, iyẹn oogun abẹnugọngọ gbe e jade kuro nibi to wa.

Nibi iwọde ifẹhonuhan alalaafia ti wọn ṣe niluu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun, l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe Igboho ki i ṣe ọdaran, o si daju pe ijọba apapọ orileede Naijiria ni wọn mọ-ọn-mọ da a duro sinu ọgba ẹwọn orileede olomiran Benin to wa lati ọdun to kọja.

Oloye Arẹmu sọ pe awọn ti mu lẹta onikọkọ meje ọtọọtọ lọ sọdọ Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, lati ba awọn fi jiṣẹ fun Aarẹ Buhari.

Ninu ọrọ rẹ siwaju, o ṣalaye pe,
“Orukọ mi ni Oloye Kamorudeen Okiki Arẹmu, Aarẹ apapọ ẹgbẹ Agbẹkọya kaakiri agbaye.  A gbọdọ ṣe iwọde yii nitori gbogbo nnkan to n lọ lorileede yii bayii buru pupọ.
“A ti kọkọ ṣe iru iwọde yii niluu Ibadan lasiko Ọba Saliu Adetunji to ti waja bayii, koko meje la fun kabiesi nigba yẹn lati ba wa fun ijọba apapọ, ṣugbọn ẹyọ kan ṣoṣo ni wọn ṣe nibẹ, iyẹn naa si ni lori ọrọ epo bẹntiroolu, tori a ti mura silẹ fun ohunkohun to le ṣẹlẹ ti wọn ba fi kun owo epo.
“Lara koko mẹfa to ku ni atunto orileede yii, o ṣe pataki pupọ, o ya mi lẹnu nigba ti wọn ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Aarẹ Buhari, to sọ pe oun ko mọ nnkan to n jẹ atunto, a mọ pe irọ lo n pa, ṣe lo fẹẹ maa tẹsiwaju ninu bi wọn ṣe n ṣe owo Naijiria baṣubaṣu.
“Ti atunto ba wa, a maa ni awọn ọlọpaa ibilẹ, a maa ni awọn ọlọpaa ipinlẹ, idagbasoke yoo wa kaakiri agbegbe, nnkan amayedẹrun yoo kari, ọdọ awa Yoruba ni idaji owo ti wọn n na lorileede yii ti n wọle.
“Awọn Hausa sọ pe awọn ki i mu ọti bia, awa Yoruba n mu un, awọn ijọba a gba owo-ori ọja (VAT) lọwọ wa lati fi tun ọdọ awọn Hausa ṣe, nibo ni wọn ti n ṣe bẹẹ, a nilo atunto.
“A gbọdọ pada si bi ofin wa ṣe wa lọdun 1960, ohun lo dara ju fun wa, koda bi a ba gbe ẹlomiran sipo aarẹ; yala Yoruba tabi Hausa, oju kan naa la ma a wa.
“Atunto gbọdọ wa ṣaaju idibo apapọ lọdun 2023, a mọ pe ijọba apapọ ni awọn sọja, wọn ni ọlọpaa, ṣugbọn a ti sọ fun wọn pe ti gbogbo nnkan ba n lọ bo ṣe wa yii, idibo apapọ yẹn le ma waye o, wọn ko gbọdọ fi oju alaijẹ-nnkan wo wa, a mọ nnkan ti a n ṣe, a ko sa fun ẹnikẹni.
“Ẹ wo wahala aisi eto aabo, ko si aabo nibi kankan mọ lorileede Naijiria, bi awọn ajinigbe ṣe n ṣe tiwọn, ni awọn agbeniṣowo n gbilẹ si i, awopn adigunjale ko dawọ duro. Laipẹ la gbọ pe awọn adigunjale gbajọba ni Ileefẹ, ko too di pe kabiesi paṣẹ akooko ti awọn araalu gbọdọ rin, a ko le ma a ba bayii lọ.
“Bakan naa ni ọrọ Sunday Igboho. Sunday Igboho ki i ṣe ọdaran, a ti n sọ ọ tẹlẹ, a si tun maa tẹsiwaju lati sọ ọ, a mọ pe ijọba apapọ labẹ Buhari ni wọn mu Sunday Igboho silẹ si ọgba ẹwọn orileede Benin, ṣugbọn awa n sọ funjọba orileede Benin bayii pe ki wọn fi Sunday Igboho silẹ nilana ofin nipasẹ kootu kiakia, nitori ọna aitọ ni wọn gba mu un silẹ, wọn ko gbe e lọ si kootu kankan mọ, tabi ki a lo agbara ibilẹ wa lati tu u silẹ.
“Mo tun sọ ọ lẹẹkan sii, awa Agbẹkọya maa mu Sunday Igboho kuro lẹwọn orileede Benin ti wọn ko ba fi i silẹ nilana ofin, ṣe nijọba wọn kan deede maa gbọ pe Sunday Igboho ti jade kuro lọgba ẹwọn.
“Iwọde wa yii ṣi n tẹsiwaju, ipinlẹ to ba wu wa la le lọ, a ti ṣetan fun ohunkohun to ba fẹẹ ṣẹlẹ, ko si ọlọpaa kankan to le fi pampẹ ofin mu wa.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI