Wàhálà nlá tún wọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní Kwara, làwọn ọmọ ẹgbẹ́ bá yalọ APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 21, 2022

Wàhálà nlá tún wọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní Kwara, làwọn ọmọ ẹgbẹ́ bá yalọ APC


Iyalẹnu nla gidi lo tun jẹ nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Kwara lawọn ko ṣe ẹgbẹ mọ, ti wọn si ni ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lawọn n tẹle lọ.

A gbọ pe lakoko ti ẹgbẹ oṣelu PDP n mura silẹ, ti wọn si n ṣe ipalẹmọ wọn lati yan gomina wọn nijọba ibilẹ Ariwa Kwara lawọn ọmọ ẹgbẹ kẹyin si ẹgbẹ.

Wọn ni olori ọdọ lẹgbẹ naa, Adam Ibrahim; akọwe ẹgbẹ, Ibrahim Idris Ejiko, Ex-officio Muhammad kudu Muhammad; alaga ijọba ibilẹ Edu tẹlẹri, Alaaji Hussein Uman (No shaking); alaga igbimọ alatunto, Usman Manzuma, atawọn oloye ẹgbẹ mẹjọ miran la gbọ pe wọn lewaju awọn ti ko din ni ẹgbẹrun kan lo si APC.











No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI