Alaga igbimọ to n ri si aawọ to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress kaakiri Naijiria, Sẹnetọ Abdullahi Adamu ti sọ pe gbogbo awọn ti inu n bi patapata lẹgbẹ oṣelu naa lawọn yoo ba sọrọ, ti iṣọkan yoo si wa ninu ẹgbẹ.
O ni awọn lawọn ohun ti wọn gbọdọ jẹ ko wa si imuṣẹ, eyi to maa jẹ ki alaafia ati iṣọkan pada sinu ẹgbẹ naa, paapaa nipinlẹ Kwara.
Sẹnetọ Adamu lo sọrọ yii lakooko to ṣabẹwo si Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, to si loun yoo lọ ba gbogbo awọn ti inu n bi patapata ninu ẹgbẹ lati ba wọn ṣe ipade, ki wọn le fọwọ wọnu.
O ni gbogbo awọn alẹnulọrọ, oloye atawọn agbaagba ninu ẹgbẹ naa loun yoo ri pe wọn wa ni iṣọkan, ti gbogbo wọn yoo si mọ pe ẹtọ kan naa ni wọn ni gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ.
No comments:
Post a Comment