Ṣàngbá fọ́! Ìṣẹ́jú díẹ̀ kí ètò ìgbéyàwó bẹ̀rẹ̀, wọ́n jí ìyàwó ojú ọ̀nà gbé nílé pásítọ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 4, 2022

Ṣàngbá fọ́! Ìṣẹ́jú díẹ̀ kí ètò ìgbéyàwó bẹ̀rẹ̀, wọ́n jí ìyàwó ojú ọ̀nà gbé nílé pásítọ̀


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii sẹni to le sọ pato ibi ti ọmọbinrin kan to n palẹmọ fun eto igbeyawo rẹ lọwọ wa, iyẹn latigba ti awọn agbebọn kan ti jii gbe.

Ile pasitọ ṣọọṣi rẹ la gbọ pe wọn ti jiigbe, nigba yo ku wakati perete ki igbeyawo oun pẹlu ololufẹ rẹ waye.

Alẹ ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii la gbọ pe wọn ji ọmọbìnrin naa, Farmatof Paul agbe nijọba ibilẹ Bokkos, ipinlẹ Plateau.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ile pasitọ ni awọn ọmọbinrin ti wọn ba fẹẹ ṣe igbeyawo fun maa n sun mọjumọ ọjọ igbeyawo, gẹgẹ bi ilana ti wọn fi silẹ ni ṣọọṣi Christ Apostolic ti ẹkun Ngyong.

Ṣe la gbọ pe awọn mọlẹbi ọkọ ati iyawo ti fi ile po ọti, wọn ti fi ọna roka, ti ọpọ awọn alejo wọn si ti de lati ọna to jinna, lai mọ pe gbegede yoo pada gbina mọ wọn lọwọ.

Ana, ọjọ Aje, Mọnde lo yẹ ki igbeyawo ọhun waye, ṣugbọn ti wọn lawọn agbebọn yawọ ile pasitọ naa ni nnkan bi agogo mọkanla ku iṣẹju mẹẹdogun, ti wọn si ji Farmat nikan salọ.

Lara awọn to fi iṣẹlẹ yii to wa leti sọ pe ede Fulani lawọn to ji ọmọbìnrin naa gbe salọ n sọ nigba ti wọn wọle. Bẹẹ la gbọ pe iwadii awọn ọlọpaa ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ.

Gunmen kidnap bride at pastor
 
Gunmen kidnap bride at pastor
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI