Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, ẹka ti Rapid Response Squad (RRS) ti kede sita wi pe ọwọ awọn ti tẹ gbajugbaja ọga onimọto nipinlẹ Eko, Kunle Poly ati Sego lonii, ọjọ Aje, Mọnde.
L'Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii la gbọ pe Kunle Poly ati awọn ọmọ ẹyin rẹ da wahala nla silẹ lagbegbe Idumọta nipinlẹ Eko, nibi ti awọn ara agbegbe naa ti juba ehoro, ti wọn si pa ẹnikan danu.
A gbọ pe ibi ti Kunle Poly, Sego ati awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ awakọ NURTW ti n ṣe ipade lọwọ lawọn ọlọpaa ti lọ ko wọn.
Latigba naa la gbọ pe awọn ọlọpaa ti n wa Kunle Poly atawọn ọmọ ẹyin ẹ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ bayii sọ pe wọn ti gbe Kunle Poly ati Sego lọ si ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti Zone II, Onikan, nipinlẹ Eko.
No comments:
Post a Comment