Wolii Elijah Babatunde Ayọdele to jẹ olori ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church to wa ni Eko ti sọ pe ki gbogbo ọmọ ilẹ Afirika, paapaa awọn mẹkunnu lọ fi ọkan wọn balẹ, nitori pe owo sinẹnti yoo lọ silẹ laipẹ.
Olori ijọ INRI lo ju asọtẹlẹ yii sita fun ọdun tuntun ti a wa ninu ẹ yii, to si ni ileeṣẹ simẹnti ti yoo figagbaga pẹlu ileeṣẹ simẹnti Dangote yoo dide.
Gbajigbaja Wolii agbaye naa sọ pe owo simẹnti yoo ṣe segesege debi wi pe ileeṣẹ simẹnti miran yoo dide lati gba ipo mọ Dangote lọwọ.
No comments:
Post a Comment