Ọmọọba Abubakar, Olumide Ìbítóyè di amúgbálẹ́gbẹ́ gómìnà Kwara lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú - IROYIN AWIKONKO

Tuesday, January 11, 2022

demo-image

Ọmọọba Abubakar, Olumide Ìbítóyè di amúgbálẹ́gbẹ́ gómìnà Kwara lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú

IMG_ORG_1641929333775

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti bu ọwọ lu Ọmọọba Suleiman Abubakar, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Sai Kayi ati Olumide Daniel Ibitoye gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ pataki lori ọrọ oṣelu ni ẹkun aarin gbungbun (Special Assistant Political for Central Senatorial District).
 
Oni tii ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni gomina kede awọn mejeeji ọhun ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita fawọn akọroyin.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti jẹ ka mọ pe lẹyin bi oṣu meloo kan ti wọn yan Malaamu AbdulKareem Yusuf  Danhawa, fun ẹkun aarin gbungbun Ariwa, ni wọn yan awọn meji yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *