Pupọ awọn to gbọ nipa ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrinla kan, Favour Iwuozor ti wọn lo ji ọmọ ọga rẹ, ọmọ ọdun meji salọ kuro l'Ekoo ni wọn n fi ọrọ buruku ranṣẹ sii, lori iwa ọdaju to hu naa.
Ipinlẹ Imo lọhun la gbọ pe Favour fẹẹ ji ọmọ naa gbe salọ, ṣugbọn ti ọwọ palaba rẹ pada segi lọjọ Aje, Mọnde to kọja.
AWIKONKO gbọ pe obinrin ẹlẹyinju aanu kan lo ri Favour nibi to ti n tọrọ owo pẹlu ọmọ naa lagbegbe Yaba, ipinle Eko, to si beere ohun to ṣẹlẹ, iyẹn lọjọ kejilelogun, oṣu kejila, ọdun to kọja.
Wọn ni ohun ti Favour sọ fun obinrin ọhun, Arabinrin Victoria Nwafor ni pe mama ati baba awọn ti ku sinu ijamba mọto, ati pe oun nikan loun n da tọ aburo oun, ti ko si si oluranlọwọ kankan.
Pẹlu oju aanu ni obinrin yii fi mu Favour ati ọmọ meji yii lọ sile ẹ to wa ni Ṣagamu lati tọju wọn. Ṣadede ni wọn sọ pe awọn iṣesi Favour bẹrẹ sii mu ifura dani, to si tun di awọn ẹru ti obinrin naa ra fun wọn pẹlu erongba lati na papa bora.
Asiko ti wọn lo fẹ juba ehoro lọwọ palaba rẹ segi.
Victoria ko ro o lẹẹmeji to fi gba teṣan ọlọpaa lọ lati lọ fi to wọn leti pe ohun tuntun toun tun ṣẹṣẹ pade ree. Awọn ọlọpaa lo pada fọrọ wa Favour lẹnu wo, to si jẹwọ fun wọn pe ṣe loun ji ọmọ ọdun meji naa gbe nibi toun ti n ṣiṣẹ ọmọ-ọdọ lọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila, ọdun 2021.
O loun fẹẹ gbe e lọ si ilu Amraku Umorsu to wa nijọba ibilẹ nipinlẹ Imo. Bẹẹ lo sọ pe inu ṣọọṣi loun ti lọ ji ọmọ ọhun gbe lakooko ti isin n lọ lọwọ
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn fi Favour ranṣẹ sawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko lati tubọ ṣe iwadii lori ọmọ yii, ki wọn le gbe igbesẹ to ba yẹ lori rẹ, ati pe ki wọn wa awọn obi ọmọ yii kan.
No comments:
Post a Comment