Owọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ọkunrin kan, Ogbẹni Oyedele Nutai Joseph, ati iyawo rẹ, Elizabeth Joseph lori ẹsun wi pe wọn ko tọọgi lọ sileewe ọmọ wọn lati lu olukọ kan lalbubami.
AWIKONKO gbọ pe ile ẹkọ girama ti Toyon, iyẹn Toyon High school to wa labule Ere, nijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta, ipinlẹ Ogun la gbọ pe awọn mejeeji ko tọọgi lọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọkan lara awọn olukọ ile ẹkọ girama naa, Ọgbẹni Abel Thomas lo lu ọmọ awọn obi yii ti wọn pe orukọ rẹ ni Joshua Joseph, ẹni ti wọn sọ pe ipele to gbẹyin lo wa nile ẹkọ girama naa {SS3}, lori ẹsun aṣemaṣe.
Wọn ni igba ti ọmọ naa dele, lo sọ fun awọn obi rẹ wi pe olukọ kan lu oun, to si ni lilu naa dun oun pupọ.
Pẹlu ibinu ni wọn sọ pe awọn obi yii fi lọ ko awọn tọọgi lorita, ti wọn si yawọ ileewe naa, nibi ti wọn ti lu olukọ naa lalubami, koda, ti wọn tun fọ gilaasi mọto ọkan lara awọn olukọ ti wọn pe orukọ rẹ ni Jọlayẹmi Sunday nibẹ.
Nibi wahala yii la gbọ pe awọn eeyan ti sare ranṣẹ sawọn ọlọpaa, ti wọn si lawọn ọlọpaa naa ko fi ọrọ yii falẹ rara to fi di pe wọn gbera lọ sibẹ.
A gbọ pe kete ti wọn ti foju kan mọto awọn ọlọpaa lọọkan, ni gbogbo wọn ti na papa bora, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ Oyedele ati iyawo rẹ, Elizabeth.
Nibẹ ni wọn ti sọ pe olukọ ko ni aṣẹ lati lu akẹkọọ kankan, depodepo ọmọ awọn, eyi to lo bi awọn ninu pupọ.
A gbọ pe ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa wa awọn tọọgi ọhun, lati le fi wọn jofin, to si paṣẹ pe ki awọn obi yii lọ foju ba ile ẹjọ lati gba idajọ to tọ si wọn.
No comments:
Post a Comment