Ọgbọn ọjọ ni Kunle Poly atawọn meji yoo lo lọgba ẹwọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, January 29, 2022

Ọgbọn ọjọ ni Kunle Poly atawọn meji yoo lo lọgba ẹwọn


Ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Yaba nipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa lọ ti Alaaji Adekunle Lawal ti ọpọ awọn eeyan mọ si Kunle Poly si ahamọ wọn fun ọgbọn ọjọ gbako lori wahala to ṣẹlẹ lagbegbe Idumọta laipẹ yii.

Yatọ si Kunle Poly, ile-ẹjọ tun paṣẹ pe awọn meji tọwọ tẹ pẹlu Kunle Poly ni ki wọn jọ wa lahamọ ọlọpaa naa titi digba ti igbẹjọ yoo tun pada waye.
 
Bẹ o ba gbagbe, l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ to kọja lọ ni wahala nla kan bẹ silẹ lagbegbe Idumọta, nibi ti wọn ti pa eeyan kan danu, ti ọpọ awọn eeyan si farapa yannayanna, eyi ti wọn sọ pe wahala naa ko ṣẹyin Kunlẹ Poly to jẹ alaga ẹgbẹ awakọ NURTW, ẹka ti Lagos Island Branch 'B'.

AWIKONKO gbọ pe olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Onikan, l'Ekoo, iyẹn Zonal Monitoring Unit, Zone 2 ni Kunle Poly atawọn meji ọhun yoo wa, nibi ti wọn yoo ti maa gbatẹgun alaafia.
 
Ọmọọba Idowu Onikoyi Johnson ati Agboọla Akeem Kosọkọ lawọn meji ti yoo wa lọgba ọlọpaa, gẹgẹ bi Onidajọ Linda Balogun ṣe paṣẹ rẹ.

Agbẹjọro ọlọpaa, Mọrufu Animashaun lo pe ẹjọ naa, to si ni awọn eeyan naa jẹbi ẹsun ọdaran ninu iwe ofin ti ọlọpaa tọdun 2020 ati ti orileede yii tọdun 1999.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI