Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, nipinlẹ Ogun, Ọmọwe Sikirulai Ọlawale Ogundele ti sọ pe bi wọn ṣe pa ọba alaye kan saarin ilu laipẹ yii ti fi han daju wi pe Gomina Dapọ Abiọdun ti kuna patapata.
Bẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lawọn kan lọ dena de Olu tilu Agodo nijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ naa, ti wọn si dana sun kabiyesi, Ọba Ayinde Ọdetọla, pẹlu awọn mẹta miran.
Ogundele, nigba to n sọrọ l'Ọjọru, Wẹsidee, ana sọ pe iṣẹlẹ ipaniyan, ijinigbe, pẹlu bi wọn ṣe pa kabiyesi to jẹ olori ilu, ti wọn tun dana sun un mọ inu mọto pẹlu awọn mẹta miran ti fi han daju gbangba wi pe Dapọ Abiọdun ko mọ nnkankan nipa iṣejọba.
O sọ pe eto aabo labẹ iṣakoso gomina yii ti mẹhẹ patapata, o si ti doju bọlẹ kọja afẹnuroyin, tabi ohun tawọn eeyan tun le maa dawọ bo mọlẹ.
Siwaju sii lo sọ pe kẹnikẹni ma ṣe gba ọrọ Gomina Abiọdun gbọ pe wi pe alaafia wa nipinlẹ Ogun lori ọrọ aabo, nitori pe ko sẹni to le sun, ko diju mejeeji lakoko ijọba Dapọ Abiọdun, to si ni eyi jẹ arapa ikuna nla ti ijọba yii ni.
No comments:
Post a Comment