Ó tán o! Ilé-ẹjọ́ ti da ẹ̀sùn tí Bọ́lárìnwá pe APC danù ní Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, January 19, 2022

Ó tán o! Ilé-ẹjọ́ ti da ẹ̀sùn tí Bọ́lárìnwá pe APC danù ní Kwara


Ile-ẹjọ giga ti ipinlẹ Kwara, eyi to wa nilu Ilọrin ti da ẹjọ kan ti alaga igbimọ fidihẹ fẹgbẹ oṣelu All Progressives COngress, APC tẹlẹri, Bashir Ọmọlaja Bọlarinwa pe alaga fidihẹ ẹgbẹ naa, Alaaji Abdullahi Samari ati alaga apapọ ẹgbẹ naa, Mai Mala Buni lori ẹsun wi pe wọn yọ oun nipo.

Bẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kọkandinlọgbọn, ọsu kin-in-ni, ọdun 2021 ni awọn mọkanla kan ninu ẹgbẹ naa ti pe ẹjọ yii, nibi ti wọn ti n sọ pe ọna ti wọn gba yan Abdullahi Samari, gẹgẹ bi alaga igbimọ fidihẹ fẹgbẹ naa ko ba ofin ati ilana mu.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ lonii, Ọjọru, Wẹsidee, Onidajọ S. M. Akanbi, paṣẹ pe ẹsun naa ko lẹsẹ nilẹ, ati pe ṣe ni wọn tun fi akoko ile-ẹjọ ṣofo.
 
Fun idi eyi, Onidajọ Akanbi sọ pe ki awọn olupẹjọ lọ san owo itanran, paapaa julọ, o tun sọ pe wọn ko gbe awọn igbesẹ to yẹ nipa biba awọn agbaagba sọrọ lati ba wọn yanju ọrọ naa ko to di pe wọn wa si ile-ẹjọ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI