Orin 'okete gbagbe ibosi, o gbegba alatẹ, o ka'wọ lori' ni wọn n kọ bayii fun ayederu ọga ologun kan ti wọn lo sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari lo fi oun sipo, iyẹn Bọlarinwa Oluṣẹgun.
Jibiti owo ti din diẹ ni miliọnu lọna ọgbọn, ₦270,000,000 la gbọ pe Bọlarinwa lu, ko to di pe ọwọ palaba rẹ segi.
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni Bọlarinwa sọ fun alakoso ileeṣẹ Kodef Clearing Resources wi pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti bu ọwọ lu oun pẹlu enikan lati di ọga ologun lorileede Naijiria.
O sọ fun ẹni naa wi pe oun nilo awọn owo kan toun yoo fi rin irin bi wọn ṣe maa fi ontẹ igbẹyin lu, ati pe oun nilo lati san awọn owo abẹtẹlẹ fawọn to le jẹ ko tete ṣee ṣe.
Wọn ni ṣe lo tun lọ ṣe ayederu lẹta kan lorukọ Buhari gẹgẹ bi eyi ti wọn fi gba a si iṣẹ.
Lẹyin o rẹyin ni aṣiri rẹ pada tu pe irọ lo n pa, eyi lo jẹ ki wọn lọ fi ọrọ rẹ to ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu, iyẹn EFCC, ko to di pe ọwọ palaba rẹ segi.
No comments:
Post a Comment