Ó ku oṣù kan gbáko, ìyàwó ojú ọ̀nà ku lójijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 4, 2022

Ó ku oṣù kan gbáko, ìyàwó ojú ọ̀nà ku lójijì


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, kayeefi nla gba a ni iku ọmọbinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ummi, ẹni ti wọn lo n palẹmọ lati lọ sile ọkọ rẹ loṣu keji, ọdun yii.

Ummi la gbọ pe oun pẹlu ololufẹ rẹ, Abdulmuhyi Bagel fẹẹ ṣe igbeyawo alarinrin lọjọ karun-un, oṣu keji, ọdun yii, ṣugbọn to pada kagbako iku ojiji airo tẹlẹ.

Ọkan lara awọn kọmiṣanna nipinlẹ Bauchi, Maryam Bagel, ẹni to jẹ ẹgbọn ọkọ iyawo oju ọna lo kede iroyin iku ọmọbinrin naa, to si ni ibanujẹ nla lo jẹ fun wọn.

A gbọ pe awọn mọlẹbi mejeeji yii ti fi ile po ọti, wọn ti fi ọna roka lori igbeyawo ọhun, ti wọn si ti mu oriṣiriṣi aṣọ ti wọn yoo wọ lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI