Nítorí tí kò fẹ́ẹ́ gba oyún, Wàsíù rán agbanipa láti pa ìyàwó rẹ̀ danù toyún-toyún - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 4, 2022

Nítorí tí kò fẹ́ẹ́ gba oyún, Wàsíù rán agbanipa láti pa ìyàwó rẹ̀ danù toyún-toyún


Pakopako bayii ni baale ile, ẹni ọdun marundinlogoji kan, Eluyera Wasiu n wo lagọ ọlọpaa laipẹ yii, ni kete tọwọ ọlọpaa tẹ ẹ lori ẹsun wi pe o fẹẹ pa iyawo ẹ to wa ninu oyun, nitori ti ko fẹẹ gba oyun naa.
 
Ilu Ogijo, nipinlẹ Ogun niṣẹlẹ yii ti waye lọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 ti a wa yii.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni ṣe ni Wasiu ledi apo pọ pẹlu ọrẹ rẹ, Adeniyi Samuel lati pa iyawo rẹ, Bọla Taiwo, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn danu, ki erongba rẹ le wa si imuṣẹ.
 
AWIKONKO gbọ pe, o ti pẹ ti Wasiu ati Bọla ti n fẹ ara wọn, ṣugbọn ṣadede ni ija de si aarin wọn, ti onikaluku wọn si lọ lọtọọtọ. Gbogbo igbiyanju awọn eeyan lati ba wọn yanju ẹ lo ja si pabo.
 
Lẹyin ti wọn lawọn mejeeji tuka la gbọ pe Wasiu fẹ iyawo miran, to si n ba igbesi aye rẹ lọ. Laipẹ yii ni wọn sọ pe awọn mejeeji tun pada pade, ti wọn si yanju aawọ to wa laarin wọn. Nibi ti wọn ti n ba ifẹ to wa laaarin wọn lọ, la gbọ pe Bọla ti loyun fun Waisu.
 
Gbara ti Wasiu gbọ pe Bọla ti loyun foun, lo ti bẹrẹ sii bẹbẹ pe ko lọ yọ oyun naa danu, ṣugbọn ti wọn niyẹn sọ pe oun ko le yọ oyun yii. Gbogbo ọna la gbọ pe Wasiu gba lati fi majele yọ oyun naa kuro lara Bọla, ṣugbọn to pada ja si pabo.
 
Nigba to rii pe pabo ni gbogbo igbesẹ toun n gbe n ja si, lo jẹ ko ranṣẹ pe ọrẹ rẹ, Adeniyi lati ba a pa Bọla danu, to si ṣeleri wi pe oun yoo fun un ni ẹgbẹrun mẹwaa naira gẹgẹ bi owo iṣẹ, eyi ti wọn ni o ti san ẹgbẹrun marun-un ṣaaju.
 
Wọn ni bi Adeniyi toun nilo owo ṣe gba ẹgbẹrun marun-un naira naa, lo ti naa jẹ, ti ko si ṣiṣẹ ti wọn gbe fun un. Igba ti wọn ni ko tete ṣiṣẹ yii la gbọ pe Wasiu lọ ba a lati gba owo rẹ pada, eyi ti wọn ni ṣe ni ọrọ naa di ariwo, to si dija igboro.
 
Nigba ti wọn ni agbara awọn ara adugbo ko ka awọn mejeeji, lo mu ki wọn ranṣẹ pe awọn ọlọpaa, ti wọn si lọ ba awọn mejeeji. Tẹsan ọlọpaa la gbọ pe Adeniyi ti jẹwọ gbogbo ohun to pa wọn pọ.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ lori awọn mejeeji, ko to di pe wọn foju wọn ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii lati gba idajọ to ba tọ si wọn.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI