Níbi tí gendekunrin yìí ti n digunjalè lọwọ́ Àmọ̀tẹ́kùn ti tẹ̀ ẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 2, 2022

Níbi tí gendekunrin yìí ti n digunjalè lọwọ́ Àmọ̀tẹ́kùn ti tẹ̀ ẹ́


Ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo ti wọn pe ni ti olohun gan-an lo de ba gendekunrin ti ẹ n woju rẹ yii, nitori pe akooko toun pẹlu ẹmẹwa rẹ n digunjale lọwọ lopopona marosẹ ipinlẹ Ọṣun si Ondo lọwọ palaba rẹ segi.
 
AWIKONKO gbọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, iyẹn Furaidee to gbẹyin ninu ọdun 2021 gan-an lọwọ ẹṣọ alaabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun tẹ ẹ.

Wọn ni oun pẹlu awọn ẹmẹwa rẹ ti da mọto akero lọna, wọn si ti n ṣe wọn bi ọṣẹ ṣe n ṣoju, ko to di pe awọn Amọtẹkun ba wọn nibẹ.
 
A gbọ pe ni kete ti wọn ti kofiri mọto awọn Amọtẹkun naa ni wọn ti juba ehoro, ṣugbọn to jẹ pe ẹnikan ṣoṣo yii lọwọ tẹ laaarin wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI