Ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku ati iwa jibiti lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin kan, Michael Jackson, ẹni ti wọn ni ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara lọ.
EFCC sọ pe iṣẹ awọn to n mu ode ariya dun pẹlu awọn orin igbalode ọlọkan-o-jọkan, tii ṣe Dick Jockey ni Michael fi n boju fawọn eeyan wi pe oun n ṣe, lai mọ pe iṣẹ jibiti ori ayelujara gangan lo yan laayo.
Wọn ni oogun abẹnugọngọ ajẹbiidan lo n lo lati gba owo lọwọ awọn eeyan lori ikanni ayelujara, ati pe orukọ kan to jẹ ti obinrin, iyẹn Ella lo fi n pe ara rẹ fawọn alaimọkan.
Agbẹnusọ fun EFCC, Wilson Uwujaren to fi iṣẹlẹ yii to wa leti sọ pe mọto Toyota 4-runner kan, mọto Honda Accord kan, Kọmputa alagbeeka, foonu olowo iyebiye to fi owo jibiti ra ni wọn ri gba lọwọ ẹ ni kete ti ọwọ palaba rẹ segi.
Bẹẹ lo sọ pe ko ni pẹ ti yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari lori rẹ.
No comments:
Post a Comment