Ibanujẹ nla lọjọ Aiku , Sannde, ọsẹ to kọja yii jẹ nigba ti iya kan ati awọn ọmọ rẹ meji padanu ẹmi wọn sinu ijamba mọto to waye lopopona Ṣagamu silu Benin.
Nnkan bi agogo mejila aabọ ọsan la gbọ pe awọn eeyan naa padanu ẹmi wọn sinu ijamba tirela nla Hovo kan pẹlu jiipu Ford niwaju ileepo MRS to wa ni Itako, Ijẹbu Ifẹ.
Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ẹṣọ oju popona, TRACE nipinlẹ Ogun lakooko to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe awakọ jiipu naa lo sare wọ abẹ tirela naa lọ lori ere asapajude.
Akinbiyi sọ pe awọn mẹrin lo kagbako ijamba yii, ṣugbọn to jẹ awọn mẹta ninu wọn lo ku loju ẹsẹ, ti ẹnikan yooku si farapa yannayanna.
No comments:
Post a Comment