'Ija d'opin, ogun si tan' lorin ti awọn agba ati ogbontarigi oṣerebinrin meji nni, Iyabọ Ojo ati Faithia Williams n kọ bayii, pẹlu bi ija to wa laaarin wọn lati bi ọdun meji sẹyin ṣe fori ṣanpọn, ti wọn si di ọrẹ pada.
Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ laaarin awọn oṣẹrebinrin meji yii, ọdun 2020 ni wahala bẹ silẹ laaarin wọn, ti awọn mejeeji si bẹrẹ sii sọrọ kungbakugbe sira wọn lori ayelujara.
Ohun tawọn eeyan n sọ nigba naa ni pe ọkunrin olowo kan lo dija silẹ laaarin wọn, ṣugbọn ti Faithia sọ pe oun ko le ba ẹnikẹni ja nitori ọkunrin.
A gbọ pe bi ija awọn mejeeji ṣe pari bayii, ko ṣẹyin alaga ẹgbẹ awọn onimọto NURTW nipinlẹ Eko, Alaaji Musiliu Akinsanya ti ọpọ awọn eeyan mọ si MC Oluọmọ ati agba oṣere nni, Ẹbun Oloyede ti awọn eeyan tun mọ si Ọlaiya.
Awọn mejeeji ni wọn ti gba ori ikanni ayelujara lọ bayii lati fi idaniloju han fsawọn ololufẹ wọn wi pe ko sija mọ laaarin awọn, ati pe gbogbo ọrọ ana ti dohun igbagbe patapata.
No comments:
Post a Comment