Kọmiṣanna f'ọrọ eto ilera nipinlẹ Kwara, Dọkita Raji Razaq ti bẹrẹ abẹwo s'awọn ibudo eto ilera kaakiri ipinlẹ naa, lati mọ obi ti iṣẹ de, ati bi nnkan ṣe n lọ si kaakiri ọsibitu.
Nibi abẹwo ọhun, eyi to bẹrẹ l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii ni Dọkita Raji Razaq tun ti lo anfaani rẹ lati maa bẹrẹ bawọn eleto ilera bii nọọsi ati dọkita ṣe n ṣiṣẹ wọn si.
Dọkita Raji Razaq sọ pe lati le ṣe abojuto bi awọn oṣiṣẹ eleto ilera ṣe n lo awọn ohun amayedẹrun lẹka eto ilera ni abẹwo ọhun wa fun, ati lati gbọ bi awọn araalu ṣe n jẹ igbadun si.
Lara ibi ti Kọmiṣanna naa kọkọ ṣe abẹwo si ni ọsibitu ijọba to wa nk Kaiama, nibi to ti bawọn eeyan, paapaa awọn olori agbegbe sọrọ, ti gbogbo wọn si gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq.
No comments:
Post a Comment