Orin 'Akiti the Ghost, Akiti the Lazy man', lawọn ara agbegbe ijọba ibilẹ Ọdẹda nipinlẹ Ogun n kọ fun gendekunrin kan, Adewale Adegbenro ti ọpọ awọn eeyan mọ si Akilapa, nigba tọwọ palaba rẹ segi lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
AWIKONKO gbọ pe ọdun to kọja ni wọn gba Akilapa gẹgẹ bi ọlọde lati maa ṣọ ile kan to wa lagbegbe Adigbẹ nilu Abẹokuta. Ko pẹ ti wọn lo bẹrẹ iṣẹ ninu ile naa la gbọ pe Akilapa bẹrẹ sii fimu finlẹ lori awọn dukia to fẹẹ jigbe salọ.
Wọn ni bo ṣe di ọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ọdun to kọja, Akilapa wọ inu ile naa lọ, to si ji dukia ati goolu olowo iyebiye. Gbogbo ẹru ti wọn ni Akilapa jigbe salọ ko din ni miliọnu mẹẹdogun naira, ti wọn ko si rii latigba naa.
Gbara ti awọn to gba Akilapa gẹgẹ bi ọlọdẹ ko ti rii mọ, ti wọn si ṣakiyesi awọn dukia to jigbe, ni wọn ti gba teṣan ọlọpaa Adigbẹ, ati ileeṣẹ ọlọpaa CIID Annex to wa ni Alagbọn nipinlẹ Eko lọ lati fi to wọn leti.
Awọn ọlọpaa Alagbọn yii ni wọn ranṣẹ oṣiṣẹ So-Safe Corps fun iranlọwọ iwadii wọn.
Nigba ti aṣiri maa pada tu, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu ti a wa ninu ẹ yii lọwọ palaba Akilapa segi lagbegbe kan nilu Ọdẹda.
Iyalẹnu ni wọn lo jẹ fun gbogbo awọn ara agbegbe yii, nigba ti wọn pada mọ pe ọdaran pọmbele ni Akilapa, ati pe ṣe lo wa farapamọ sibẹ, ki aṣiri rẹ ma ba a tu sita.
Ni bayii, a gbọ pe wọn ti fa Akilapa le awọn ọlọpaa Alagbọn naa lọwọ lati tẹsiwaju iwadii wọn.
No comments:
Post a Comment