Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó ṣekú pa Ọba alayé l'Ógùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 27, 2022

Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tó ṣekú pa Ọba alayé l'Ógùn


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe iwadii awọn ti bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lati mọ awọn to lọwọ si bi wọn ṣe pa Ọba Ayinde Ọdẹtọla, Olu tilu Agodo, to wa nijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ naa nipakupa.
 
Kii ṣe bi wọn ṣe pa Kabiyesi yii, Ọba Ọdẹtọla lo n jẹ kayeefi, bi ko ṣe pe wọn tun dana sun un mọ inu mọto ẹ lakooko to wọnu ilu wa, ti ko si sẹni to le daa mọ wi pe kabiyesi ni, eyi gan-an lo n kọ awọn eeyan lominu pupọ.
 
Lara awọn awuyewuye to ta si AWIKONKO leti ni pe awọn kan ko fẹ Ọba Ọdẹtọla nipo gẹgẹ bi Olu tilu Agodo, wahala yii si la gbọ pe o ti wa nilẹ latigba ti wọn ti fi kabiyesi jẹ.

Ẹsun ti wọn ka si Kabiyesi lẹsẹ ni pe kii ṣe ọmọ ilu Owu to laṣẹ ati anfaani lati jẹ ọba nibẹ. Wọn ni ọmọ Ake ni, nitori naa, ko ni ẹtọ kankan lati jẹ ọba.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Olu Itori, Ọba Akorede Akamọ sọ pe irọ to jinna si otitọ ni wi pe wahala wi pe wọn ko fẹ ọba naa nipo wa nilẹ, ati pe wahala to wa nilẹ ko ni nnkan ṣe pẹlu ọrọ ipo ọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI