Ilu Eko ni Nurudeen n gbe, ipinlẹ Ogun lo ti ji ọkada gbe ko to ha sọwọ agbofinro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, January 29, 2022

Ilu Eko ni Nurudeen n gbe, ipinlẹ Ogun lo ti ji ọkada gbe ko to ha sọwọ agbofinro


Ẹpa ko boro mọ fun baale ile kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Nurudeen Tajudeen nigba tọwọ eleto aabo ipinlẹ Ogun, So-Safe Corps, ẹkun tijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta tẹ ẹ, to si n bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ.

Ojule kejila, adugbo Olowookere, Orile-Agege nipinlẹ Eko la gbọ pe Nurudeen, ọmọ bibi Iganna nipinlẹ Ọyọ naa n gbe. Ko si niṣẹ meji ju ko maa ji ọkada ọlọkada gbe kaakiri ipinlẹ Ogun.
 
A gbọ pe ọkada Bajaj ti nọmba idanimọ rẹ jẹ FJ 8291, eyi ti Nurudeen jigbe gbẹyin lo pada tu aṣiri rẹ sita lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii, iyẹn Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ yii.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe nnkan bi agogo mẹjọ kọja ogun iṣẹju, alẹ ọjọ naa ni Nurudeen ji ọkada yii gbe niwaju ọtẹẹli Mokland to wa ni Ọta, nibi ti wọn gbe e si.
 
Wọn ni bo ṣe gbe ọkada naa, lawọn eeyan ti rii, ti wọn si sare ranṣẹ sawọn eleto aabo So-Safe Corps to wa nitosi, ko to di pe wọn sare tẹle lẹyin.
 
Bi ọwọ ṣe tẹ ẹ lo ti bẹrẹ sii dọbalẹ bẹbẹ pe ki wọn foju aanu wo oun, nitori pe iṣẹ eṣu ni, ati pe oun ko mọ igba ti oun ji ọkada naa gbe.
 
Mọruf Yusuf to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ So-Safe Corps sọ pe ọga awọn Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa Nurudeen le awọn ọlọpaa ẹkun Sango lọwọ lati tẹsiwaju iwadii lori ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI