Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa Rapid Respond Squad, RRS nipinlẹ Eko ti tẹ gendekunrin mẹta kan, ti wọn ko niṣẹ meji ju idigunjale lọ kaakiri igboro lagbegbe Agege, ipinlẹ naa.
A gbọ pe ori afara lawọn mẹtẹẹta ti digun gba owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira, foonu mẹta ọtọọtọ ati aago ọwọ lọwọ ẹnikan.
Ridwan Imran, ọmọ ogun ọdun; Lukman Abiọdun, ọmọ ọdun mejidinlogun, ati Abdulahi Isa, toun naa jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun lawọn mẹtẹẹta.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ṣe lawọn mẹtẹẹta dena de ẹni naa lori afara, tiyẹn si gbiyanju lati na papa bora, ṣugbọn ti wọn pada lee mu, ko to di pe wọn yọ ibọn si i lati gba gbogbo nnkan to ko dani.
A gbọ pe Lukman Abiọdun lo lewaju ikọ ẹlẹni mẹrin naa, eyi ti awọn yooku ti salọ lọjọ naa. Nnkan bi aago mẹsan alẹ niṣẹlẹ yii waye lori afara Iṣhẹri si garaaji Berger.
Wọn ni ṣe ni wọn kọkọ sunmọ ẹni naa wi pe ko fun awọn lowo, ṣugbọn to loun ko lowo lọwọ. Nigba to rii pe adigunjale ni wọn, idi ree to fi juba ehoro, ṣugbọn ti wọn pada rii mu lagbegbe papa iṣere Agege.
Bi wọn ṣe rii mu ni wọn ti fọ igo mọ ọn lori, ti wọn si tii danu kọta, ko to di pe wọn gba gbogbo dukia ọwọ rẹ.
Gbogbo nnkan ti wọn gba lọwọ ẹ la gbọ pe ko din ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta {N600,000:00} naira.
No comments:
Post a Comment