Aarẹ Muhammadu Buhari ti orileede Naijiria ti sọ pe ko sewu loko, afi giri aparo, nitori pe pẹlu ọrọ toun ba ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles sọ lonii ti fi han daju pe wọn yoo ṣe daadaa.
Buhari lo sọ eyi di mimọ lori ikanni ayelujara rẹ laipẹ yii wi pe oun ti ba ikọ Super Eagles ati akọnimọngba wọn, Austin Eguavoen sọrọ.
O ni inu oun dun lati ba balogun ikọ naa, Ahmed Musa, Aarẹ Nigerian Football Federation (NFF), Amaju Pinnick, ati aṣoju Naijiria silẹ Cameroon, Ajagunfẹyinti Abayọmi Olonisakin sọrọ.
Siwaju sii lo sọ pe oun dupẹ lọwọ wọn fun bi wọn ṣe n gbe ogo Naijiria ga, toun si tun gbadura fun wọn wi pe wọn yoo tayọ ninu idije to n lọ lọwọ.
No comments:
Post a Comment