Èyí gan-an làṣírí ikú tó pa Ìyábọ̀ Òkò, àgbà òṣèré tíátà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 6, 2022

Èyí gan-an làṣírí ikú tó pa Ìyábọ̀ Òkò, àgbà òṣèré tíátà


Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe agba oṣerebinrin nni, Sidikat Odukanwi, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Iyabọ Oko ti jade laye lẹni ọdun mejilelọgọta, ṣugbọn ohun to ṣokunfa iku rẹ gan-an lo ṣokunkun sawọn eeyan.

Alẹ ana, iyẹn Ọjọru, Wẹsidee ọsẹ yii ni mama naa jade laye, lẹyin ọpọlọpọ ọdun to ti wa lori aisan rọparọsẹ.

Ọkan lara awọn ọmọ Iyabọ Oko, iyẹn Bisi Aisha lo fidi iroyin iku mama naa mulẹ lori ikanni ayelujara ti Instagiraamu lalẹ ana, iyẹn ni kete to jade laye.

Bisi lakoko to n fi iroyin iku mama rẹ to gbogbo aye leti kọ ọ pe:
"Iya mi ti lọ. Sun un re mama. Ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere mama mi."

Bakan naa ni Folukẹ Daramọla-Salakọ toun naa jẹ oṣere tiata, ẹni to maa n fi ajọ alaanu rẹ ṣe iranwọ fawọn eeyan, paapaa awọn to ku diẹ kaato fun nidi iṣẹ tiata naa tun kọ ọ sita wi pe lotitọ ni.

O kọ ọ pe "Atipe lẹyin-o-rẹnyin a padanu rẹ... O di gbere Iyabọ Oko, a gbiyanju agbara wa, ṣugbọn Ọlọrun lo ye."

Ṣaaju asiko yii ni ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe naa, Ọlamide, ti ba akọroyin kan sọrọ nipa aisan mama rẹ, to si ni aisan rọparọsẹ ti awọn oloyinbo n pe ni 'Ischaemic Stroke' lo n ṣe mama oun, ati pe o ti to ọdun marun-un bayii, to ti wa lori ẹ.
 
Ọlamide sọ pe mama oun ko fẹ ki wọn pariwo sita fun araye, debi wi pe wọn yoo wa maa da owo jọ foun, idi ree to fi lawọn mọlẹbi nikan lo mọ si.
 
Siwaju sii lo sọ pe ohun kan ṣoṣo to koba mama oun ni pe kii lọ fun ayẹwo loore-koore, ati pe nitori aisi mọto to le maa gbe e lọ ni, to si bẹ awọn eeyan nigba naa wi pe ki wọn da owo lati ra mọto fun mama oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI