Ẹlẹdàá mi kò ní jẹ́ kí wọ́n tú Sunday Ìgbòho sílẹ̀ láhàámọ́ tó wà - Seriki Fulani Igangan pariwo síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, January 22, 2022

Ẹlẹdàá mi kò ní jẹ́ kí wọ́n tú Sunday Ìgbòho sílẹ̀ láhàámọ́ tó wà - Seriki Fulani Igangan pariwo síta


Seriki Fulani nilu Igangan to wa lagbegbe Ibarapa, Oke-Ogun nipinlẹ Ọyọ, Abdulkadir Saliu, ti sọ pe ẹlẹdaa oun ko ni jẹ ki wọn tu Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ, tii ṣe Sunday Igboho silẹ lahamọ to wa.

Bẹ o ba gbagbe, Seriki Fulani ilu Igangan yii  ni Sunday Igboho fun ni gbedeke ọjọ meloo kan lati filu Igangan silẹ, iyẹn lọdun to kọja.

Abdulkadir sọrọ yii lakooko to n ba akọroyin Daily Trust sọrọ ninu ifọrọwọrọ to ṣe, to si loun ko le gbadura ki Igboho ri itusilẹ gba kuro lahaamọ awọn agbofinro orileede olominira Benin ti wọn fi i si lati oṣu keje, ọdun to kọja.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:

“O wa lakọọlẹ pe ọmọ Yoruba mẹta pere ni wọn ji gbe niluu Igangan latigba ti wahala ọhun ti bẹrẹ, ẹya Fulani ni gbogbo awọn yooku ti wọn n ji gbe.

“Inu iṣẹlẹ yẹn ni aburo mi doloogbe si. Ọpọ awọn eeyan wa ni wọn pa danu. Maaluu ti wọn ji, to sọnu tabi ti wọn ṣe baṣubaṣu ko niye. Ọrọ ibanujẹ gidi ni fun mi. Gbogbo ohun ti mo fowurọ aye mi ko jọ ni mo padanu lasiko akọlu ti Sunday Igboho ṣe si Gaa wa yẹn. Atigba naa ni aye ti nira fun mi titi dasiko yii.

“O da mi loju pe oun (Sunday Igboho) naa yoo ti maa geka abamọ jẹ fun ohun to ṣe yẹn bayii. Ko si ibi ti ọmọ Naijiria eyikeyii ko le gbe lorileede yii, gbogbo igba ni mo si ti maa n sọ pe awọn ọdaran wa kaakiri ni. Bi ọdaran ṣe wa ninu awọn ọmọ Yoruba naa lo wa laarin awa Fulani. Idi niyẹn to fi yẹ kijọba ṣiṣẹ lati wa awọn to jẹ ọdaran gan-an lawaari, ki wọn si fi wọn jofin.

“Mi o faramọ ki wọn tu Sunday Igboho silẹ lahaamọ, ko si dun mọ mi bawọn eeyan ṣe n beere pe kijọba tu u silẹ. Iya toun ati awọn ẹmẹwa ẹ fi jẹ mi kọja afẹnusọ, mo si fẹ ki idajọ ododo waye lori ọrọ naa.

“Loootọ ni Sunday Igboho fun mi ni gbedeke lati filu silẹ nigba yẹn, mi o si ko iyan ọrọ naa kere, ṣugbọn nigba ti mo lọọ fẹjọ sun awọn agbofinro, wọn fi mi lọkan balẹ pe ko sewu, pe kinni kan ko le ṣẹlẹ si mi. Loootọ lọjọ naa, awọn ọlọpaa bii mẹrinla ni wọn ko wa lati pese aabo, bi awọn ọmọọṣẹ Sunday Igboho ṣe bori wọn jọ mi loju.

“Ko sohun meji ti mo fẹ bayii ju idajọ ododo lọ.” Bẹẹ ni Seriki Fulani naa sọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI