Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nijọba ibilẹ Ariwa Kwara ti sọ pe awọn ti bu ọwọ lu Gomina Abdulrahman Abdulrazaq lati pada sipo naa lẹẹkeji, nitori pe iṣẹ ati iṣejọba rẹ n tẹ wọn lọrun.
Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Ariwa Kwara, Abẹnugọn ile ibimọ aṣofin ipinlẹ naa, atawọn alẹnulọrọ, to fi mọ awọn agbaagba ẹgbẹ ni wọn pawọpọ sọ pe awọn n fẹ Abdulrazaq lati maa tẹsiwaju ijọba lọ.
Yatọ si awọn wọnyi, awọn ọmọ ile igbimọ ipinlẹ naa to n ṣoju agbegbe Edu, Patigi, Moro, Baruten, Kaiama ko gbẹyin nibi eto ọhun to waye ni Bode Sadu.
No comments:
Post a Comment