'Ẹ ṣaanu mi, ẹ foju aanu wo mi, ẹ da aṣọ aṣiri bo mi', wọnyi lawọn ọrọ ẹbẹ to n tẹnu ayederu pasitọ kan to fi ilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun ṣe ibugbe, Timothy Oluwatimilẹhin, nigba ti ọwọ palaba rẹ segi.
Timothy ni alakoso ṣọọṣi Spirit Filled International Christian Church to wa lagbegbe Olomoore nilu Abẹokuta, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Wọn ni iyaale ile kan loun pẹlu ọkọ rẹ ja, to si lọ ba Timothy fun amọran ati adura, ṣugbọn ti wọn ni ṣe lo sọ fun un pe ko lọ ko ẹru rẹ atawọn ọmọ rẹ meji maa bọ ni ṣọọṣi.
Obinrin naa ko ro o lẹẹmeji to fi gbọ si Timothy lẹnu. Latigba naa lo ti n gbe lọdọ rẹ pẹlu awọn ọmọ rẹ mejeeji, nibi to ti lanfaani lati maa ko ibasun fun wọn lojoojumọ.
Bi aṣiri yii ṣe tu si ọkọ obinrin naa lọwọ lo ti gba ileeṣẹ awọn to n ja fun ẹtọ ọmọniyan labẹ ijọba lọ, lati fi to wọn leti. Loju ẹsẹ ni wọn ti lọ fi to awọn ọlọpaa Adatan nilu Abẹokuta leti, ko to di pe wọn lọ gbe Timothy.
Nigba tọwọ tẹ Timothy, to si rii pe ko si ọna abayọ, lo ba bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ nitori pe iṣẹ eṣu ni
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki iwadii tẹsiwaju, ki wọn si fi oju Timothy ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment