Ẹ wo bí 'ICT Innovation Hub' tíjọba Kwara n kọ́ lọ́wọ́ ṣe fẹ́ẹ́ rí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 6, 2022

Ẹ wo bí 'ICT Innovation Hub' tíjọba Kwara n kọ́ lọ́wọ́ ṣe fẹ́ẹ́ rí


Ko sẹni to ri aworan bi gbagede ti wọn yoo ti maa ṣe igbelarugẹ imọ ayelujara, iyẹn ICT Innovation Hub nipinlẹ Kwara, eyi ti gomina AbdulRahman AbdulRazaq n ṣagbatẹru kikọ rẹ siluu Ilọrin, ti ko nii mọ pe ọna ara ni wọn fẹẹ fi mu idagbasoke wọ ipinlẹ naa lẹka imọ ayelujara.

Ijọba Kwara lẹyin ọpọlọpọ iwadii ijinlẹ ati ijiroro fi ẹnu ko lati da gbagede naa silẹ, fun anfaani awọn eeyan, paapaa awọn araalu ati alejo.

Gbagede yii pese aaye alaafia fun awọn ọdọ lati le ronu jinlẹ lori ọna bi idagbasoke yoo ṣe de ba ipinlẹ Kwara lọna igbalode ti ikanisira-ẹni nipa imọ ayelujara, iyẹn tẹkinọlọji.
 
Ọdun 2022 ti a wa ninu ẹ yii gan-an ni wọn yoo pari kikọ rẹ, ti yoo si di lilo.
 
Diẹ ree lara awọn aworan naa:













No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI