Olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ Igboho ti sọ pe oun ko ni ija kankan pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ati gbogbo awọn gomina mẹfa to wa nilẹ Yoruba.
O sọ pe ija awọn ọmọ ilẹ Yoruba ti awọn Fulani darandaran n fojoojumọ pa danu bi ẹni pa eṣinṣin loun n gbe, eyi toun fi n pe fun idasilẹ orileede Oduduwa.
Ninu ọrọ rẹ fun ọdun 2022 ti a wa yii ni Igboho ti sọrọ naa, to si ni ki Aarẹ Muhammadu Buhari wa ọna abayọ ati ojutuu si iṣoro to n koju awọn ọmọ Yoruba lati ọdọ awọn Fulani darandaran.
Igboho tẹsiwaju pe ko si nnkan meji to bi ifẹhonuhan idasilẹ orileede Oduduwa, to kọja wahala tawọn ọmọ Yoruba n koju lati ọdọ awọn Fulani darandaran, paapaa awọn agbẹ.
O tun jẹ ko di mimọ pe gbogbo ọmọ orileede yii lo nilo eto aabo to peye lai fi ti ọrọ ẹlamẹya, ẹsin tabi ọrọ oṣelu ṣe.
No comments:
Post a Comment